ÀlÀyÉ lÓrÍ Òwe yorÙbÁ

49
ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ (ESIN ÒRÒ) J. ADÉBÁRE ATÓYÈBÍ B.A. (Hons.) Yorùbá (Ifè), PGDE (Ìlorin),

Upload: thalessa-lanzelotti

Post on 22-Oct-2014

198 views

Category:

Documents


6 download

TRANSCRIPT

Page 1: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

(ESIN ÒRÒ)

J. ADÉBÁRE ATÓYÈBÍ

B.A. (Hons.) Yorùbá (Ifè), PGDE (Ìlorin),

M.A. Yorùbá (Ìbàdàn)

Page 2: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

Èka Èkó Nípa Èdá Èdè àti Èdè Ilè Nàìjíríà

Yunifásítì Ìlorin,

Ìlorin, Nàìjíríà

Ní osù Ogun, Odun 2005 ni a kó te ìwé yìí jade.

ÀKÍYÈSÍ

Enikéni kò gbodò da ohunkóhun ko tàbí se èdà ohunkóhun láti inú ìwé yìí fún ìlò ara tirè láì gba àse lówó ònkòwé tàbí iléesé atèwétà tó te ìwé yìí lábé òfin tó de jíjani ní olè opoolo àti ìwé gbígbé jáde.

Page 3: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

ISBN: - 978 – 8090 – 09 - 5

Gbogbo ètó àti àse lórí rè jé ti

J. Adébáre Atóyèbí

Department of Linguistics and Nigerian Languages, University of Ilorin, Ilorin, Nigeria

E-mail: [email protected]

Eni tí a le se ìwádìí lódo re náà ni eni ti o ko ìwé yìí.

Haytee Press and Publishing Co. Nig Ltd.,

Page 4: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

154 Taiwo Road, P. O. Box 6697, Ilorin.

080-33604983,031-221801.

ÌFIJÚBÀ

Mo fi ìwé yìí júbà gbogbo ènìyàn tó kó mi ní dídá owó, ètìtè alè àti òhárára ebo nínú èdè àti lítírésò Yorùbá. A kì í júbà eni tó bá fi oògùn sínú kú. Nítorí kí isu má kùú àkúrun ni àgbè se n se ara won ni èbù.

Ìbà yín o

Gbogbo Amètò mètó.

Page 5: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ
Page 6: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

Ta ni Onkowe?

Omo bíbí ìlú Ìrágbìjí ní ìjoba ìbílè Bórípé ní ìpínlè Òsun ni J. Adébáre Atóyébí Odún 1985 ni ó gba oyè àkókó nínú ìmò ìpìlè èdá nínú Èdè àti lítírésò Yorúbá (B.A. Hons. Yorúbá) ní Yunifásíti tí Ife tí a mò sí Yunifásítí Obáfémi Awólówó lónìí. Odún 1993 ni Adébare gba Oye Dípúlómà nínú isé olùkóni (PGDE) ní Yunifásítí Ilorin.

Ònkòwé yìí gbá pé àìní ìtélórùn ní í se okùnfa ìdásílè nnkan tuntun; Èyí lo fa á tí ònkòwé yìí fí lo sí Yunifásítí Ìbàdàn láàárín odún 1994-96. Odún 1996 ni ó gba oyè ìjìnlè/Emeè nínú lítírésò Yorùbá. (M.A. Yorùbá Literature).

Adébáre ti se isé olùkó rí ní ilé-ìwé alákòóbèré àti ti girama. Oun ni Olúkó àkókó tí ó bèrè kíkó èdè àti lítírésò Yorúbá ní ilé ìwe ìjoba àpapo: Federal Government Girls, College, Owerri, Imo State ni odún 1987.

Ní báyìí, lítírésò àti àsà Yorúbá ní ó yàn ní ààyò ní: Èka Èko Nípa Èdá èdè àti Èdè ile Nàìjíríá, Yunifásítí Ìlorin, Ìlorin Nàìjíríá. Ìrírí re gégé bii akékòó àti olùkó ni ó fi ko ìwé yíí.

OPÉ FÚN OHUN GBOGBO

Page 7: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

Mo dúpé lówó gbogbo ènìyàn tí mo se agbe ìrànlówó dé òdò won nígbà tí mo jé túlè ní Ifáfitì Ifè àti ní ìgbà tí mo lo sí Ifáfitì Ìbàdàn láti fi ìmò kún ìmò léyìn gbígba òmìnira oyè àkókó nínú ìmò ìpìlè èdá nínú èdè àti lítírésò Yorùbá (Bí-Eè Yorùbá).

Òsùbà n lá ni mo gbé fún gbogbo òré, ará, àti ojúlùmò, tí won sè mí ní èbù orísìírísìí òwe láì mò pé won n kó mi ní èkó tó kàmòmò. Mo dúpé púpò lówó òré mi Àlàbí Adéfayò, ilé Amínní-wòn-oògùn ní ìlú Ìwó. Mo gbó mérìíyìírí Òwe lénu rè nígbà tí à n se isé àgùnbánirò ní ìlú Potiskum, ìpìnlè Borno (ìyen Yobe báyìí) tó wà ní ìhà àríwá Òkè Oya Nàìjíríà láàárín odún 1985 sí 1986. Bí e ti n sòrò ni mo n fetísí òwe tí è n pa. Bí e bá rí òwe yín ninú ìwé yìí, mo fé kí e mò pé mo fi se àpónlé yín ni. Mo mi sééré owó sí àwon tí wón ka isé yìí wò kó to di títè jáde.

Bí omodé bá dúpé oore àná, a rí òpòlopò òmíràn gbà. Ode tó pa eran tó n se orò, nítorí èyí tó pa ko, kí ó lè rí òmíràn pa ni. Mo dúpé púpò, mo sì ní ìrètí pé e kò ní í gbé ojú ekùn ka orí fún mi nígbà yówù tí òngbe ìmò bá tún gbe mí dé òdò yín. N kò gbàgbé eni tí ó kókó fi èro te ìwé yìí, Ògbéni M.A. Oyènpèmí (AdeMerit Business Centre, Ìlorin) àti ilé isé atèwétà tó te ìwé yìí.

Tí ìwé yìí bá bá ojú rere àwùjo pàdé èyin ni e jé kí aso mi ní orúko ní ilé aláró èdè àti lítírésò Yorùbá o. Ìdí ni pé ìwúrí ni bíbá ojú rere àwùjo pàdé ìwé yìí yóò jé fún mi láti tèsíwájú nínú kíko ìwé Yorùbá. Yorùbá kò níí jó àjórèyìn bíi iná fìtílà, àse.

J. Adebare Atoyebi.

August, 2005.

ÌTÓKA

Ìfijúbà ......................................... iii

Page 8: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

Òrò Nípa ònkòwé ......................... iv

Opé fún ohun gbogbo .................. v

Ìdí Abájò ...................................... 1

Ìfáárà .......................................... 4

Kín ni Òwe? ................................ 6

Nnkan tó mú Òwe se pàtàkì ........ 8

Ònà tí àwon àgbà fi n kó òwe jo.... 10

Bí ènìyàn se lè ní ìmò tó

múnádóko nípa òwe Yorùbá ........ 11

Bí a se máa n lo òwe Yorùbá ....... 13

Díè nínú òwe Yorùbá ................... 16-41

Page 9: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

ÌDÍ ABÁJO

Yorùbá ní bí kò bá ní ìdí, obìnrin kan kìí jé Kúmólú. Béè ni asáré inú èèkan kìí sá a lásán, bí kò bá lé nnkan, nnkan n lé e. Òpòló kìí déédé ta ìkaakà. Kì í se ìfé láti di olówó òjijì tàbí ònkòwé ní tìpá-tìkúùkù ló se okùnfà ìwé yìí. Ìdí pàtàkì méjì tàbí méta ló mú ni ko ìwé yìí.

Nnkan kínní, àkíyèsí fi hàn pé ìmò àwon akékòó òde òní lórí òwe Yorùbá kò múná dóko tó. Òpòlopò nínú won ni kò mo òwe Yorùbá, kí á tó so pé won yòó mo ìwúlò àti ònà tí ènìyàn fi lè mo òwe Yorùbá. Èyí ló fà á tí òpòlopo won kìí fí i se dáradára tó nínú àròko kíko, pàápàá jùlo lórí ìlò-èdè, nígbà tí won bá n se ìdánwò àsejáde ní ilé ìwé won.

Ní ònà kejì, kì í se àwon ìpéèrè tàbí òdó nìkan ló ní òkè ìsòro kan tàbí òmíràn lórí òwé Yorùbá. Ìrírí mi gégé bíi olùkó èdè àti lítírésò Yorùbá fi hàn pé àwon àgbà náà wà tí won nílò àlàyé tàbí ìtónisónà lórí òwe Yorùbá. A rí àgbà, pàápàá jù lo, nínú àwon alákòwé tí won ní in lókàn pé òwe tí kò bá sí nínú àwon ìwé tó wà lórí àte nípa òwe Yorùbá kì í se òwe. Bóyá, wón gbàgbé tàbí won kò mò pé kànga ogbón, òye àti ìmò nípa òwe Yorùbá kò pin sí àgbàlá enìkan. Eni kan kì í jé mo gbón-tán-mo-mò-ón-tán. Ibi tí ogbón eni kan pin sí ni ti elòmíràn ti bèrè. Èwè, bíi ohun elémìí ni èdè, bí ó se n dàgbà ni òwe rè yóò máa pò sí i. Yorùbá ní òkánjúà n dàgbà, ogbón n lo sí iwájú.

Èrò láti ran àwon akékòó èdè àti lítírésò Yorùbá lówó lórí ìmò won tí kò kún tó nípa òwe Yorùbá je kókó kan pàtàkì nínú ìdí tí ìwé yìí fi wáyé. Bákan náà ni ìwé yìí jé ìgbésè, láti tó àwon àgbà, pàápàá jù lo, àwon alákòwé tó ní ìmò díè nípa òwe Yorùbá, tí won sì n gbé ìlú nlá sónà, kí won lè mò pé òwe Yorùbá kì í se nnkan tí a lè kà tán nínú ìwé méjì tàbí jù béè lo. Òwe Yorùbá pò, kò ní ònkà rárá. Èkó àkóòkótán bíi ifá ni.

Síwájú sí i, ìwé yìí wà fún ìtósónà àwon Olùkó àti àkàgbádùn gbogbo ènìyàn tó ní ìfé èdè Yorùbá, tí òwe sì mú omú láyà won bíi omo tuntun. Orísìí olùkó mérin ni ìwé yìí yóò wúlò fún jù lo. Orísìí kínní ni àwon olùkó tó ní ìmò ìjìnlè nínú òwe Yorùbá, sùgbón tí ó sòro fún láti fi ìmò tí won ní kó elòmíràn, nítorí pé ìmò won nínú isé olùkó kò kún tó bí o ti tó àti bí o ti ye. Orísìí olùkó kejì ni àwon tí won ní ànfààní èkósé olùkó tí won sì ti ipa béè mo ènìyàn án kó, sùgbón tí won kò ní ìmò nínú òwe Yorùbá.

Orísìí olùko keta ni àwon tó di dandan fún láti kó ni ní òwe Yorùbá, sùgbón tí won ní ìsoro nítorí pé won kò ní ìmò tó nínú òwe Yorùbá àti nínú ìlànà ìkóni. ‘Ìpónjú àìsí olùkó tó múnádoko tàbí òwonnìyàn nínú èdè Yorùbá ní ilé ìwé ló sún irú àwon wònyen dé ibi kíkó akékòó ní òwe Yorùbá. Àyàbá ti ajá á fi oúnje ìdí èsù ú se ni Yorùbá kíkóni jé fún won. Orísìí olùkó kerin ni

Page 10: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

òpòlopò àwon akékòó nílé èkó isé olùkóni, tí ìmò won kò jinlè nínú òwe Yorùbá ti won sì pa èkósé olùkóni pò mó kíkó nípa òwe Yorùbá. Ìgbàgbó mi ni pé bí irú ìwé yìí bá wà ní àrówótò orísìí olùkó mérèèrin tí a ménubà yìí, yóò ràn wón lówó láti máa fi ojoójúmó wá ìmò kún ìmò, kíkóni ní òwe Yorùbá yóò sì ti ipa béè rò wón lórùn.

Bí e bá ti n ka ìwé yìí ni è ó rí ara yin he bíi ìgbín nínú èdè àti lítírésò Yorùbá, tí orísìírísìí òwe mìíràn yóò máa so sí yin lókàn bíi kúlúso. Sé bí àyàn bá fi kòngó lu òkú ìdérègbè (ewúré) tó gbé kó èjìká rè, ó di dandan kó mú ti inú rè jáde. Ó se pàtàkì kí ènìyàn ní ìfé sí òwe Yorùbá, sùgbón nnkan pàtàkì mìíràn ni pé kí ènìyàn mo ònà tó lè gbà máa ko iná mó ìmò rè lórí òwe Yorùbá kí ìmò náà má baà jóbà tàbí gò bíi isu tí a gbè ka iná, sùgbón tí a kò koná mó on kó lè jinná dénú.

Ènìyan gbé òkèrè níyì, súnmóni ni à á mo ìhùwàsí àti ìsesí eni. Enu ni aá ti í mo iyò obè. Ìwé náà nìyí lówó yín, e mu owó lápò, e rà á fún ara yín, e rà fún omo, ìyàwó, ará, òré àti ojúlúmò yín. Kíkì níí mú orí egúngún yá. Bí e bá gbà á lénu mi tí e so ó di orin, ó dájú pé ìwúrí n lá ni yóò jé láti ko ìwé mìíràn fún àkàgbádùn yín. E tó o wò, è ó ríi pé oyin momo ni o.

ÌFÁÁRÀ

Orísìírísìí nnkan ló máa n gbé èdè níyì, yálà nígbà tí a bá n sòrò ni àwùjo tàbí tí a bá ko ó sílè. Enikéni tó bá gbó èdè Yorùbá gbódò mò ón so pèlú síse àmúlò àti àfiwé nnkan tó bára won mu. Sé ohun tó bá jo ara won ni à á fi í wé ara won, èèpo èpà ló jo Pósí Èlírí, owó àti esè ìjàpá jo àran òpe. Kí á tó lè so pé ènìyàn tó gbangba sùn lóyé nínú èdè Yorùbá, eni náà gbódò mo bí a se é sòrò ní àwùjo, ìbáà se ti alákòwé tàbí ti sòròsòrò.

Nnkan tó máa n gbé èdè Yorùbá níyì yàtò sí ti èdè Gèésì àti èdè mìíràn káàkiri àgbáyé. Ìdí nìyí tí agbada èdè kan kò fi se é dín àkàrà èdè mìíràn láìmú ìdàrúdàpò àti àsìgbó wá. Onà èdè tí í fún èrò inú eni tí a so jáde lénu tàbí ko sílè nínú ìwé ní ewà yìí kì í se ohun ti ènìyàn lè fi ojó kan tàbí osù kan tàbí odún kan kó. Èkó àkóòkótán bíi ifá ni. Ìdí ni pé ogbón, òye àti ìmò nípa èdè, àsà àti ìse Yorùbá kò pin sí òdò eni kan. Bí èdè bá se n dàgbà bíi ohun ògbìn tí a gbìn sí etídò ni onà èdè inú rè náà ó máa gbòòrò sí i. Bí àwon elédè bá se n se alábàápàdé nnkan tuntun ní ònà kan tàbí òmíràn, tí won sì n fún un ní orúko láti máa se àmúlò rè ni òrò inú èdè won àti onà èdè yóo máa gbèrú síi.

Page 11: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

Yorùbá ní nnkan tó bá wu ni ní í pò lólà eni, onígba erú kú, aso rè jé òkan soso. Òwe se pàtàkì nínú onà èdè tí í gbé èdè Yorùbá níyì. Ìdí nìyí tí Yorùbá fi máa n so pé òwe lesin òrò, òrò lesin òwe, bí òrò bá sonù, òwe ni à á fi í wá a. Òwe máa n yo kókó òrò jáde.

KÍN NI ÒWE?

A lè ki òwe gégé bíi gbólóhùn tí ó fi àkíyèsí ìjìnlè ogbón, òye àti ìmò ìgbà ìwásè tàbí àtìrandéran nípa ìhùwasí àti ìsesí èdá àti òfin bí nnkan se máa n tèlé ara won hàn ní ònà tí kìí sábàa yè tàbí yípadà. A tún lè pe òwe ní ìpèdè tabí afò kúkúrú tó máa n ní ìtumò tó jinlè lókàn eni tí a bá fi sòrò fún. Síwájú sí i, òwe je afò tàbí ìpèdè nípa ìrírí èdá omo ènìyàn, tó kún fún ogbón, òtító, èkó, ìbáwí, ìkìlò, ìwúrí, àti ìmòràn tó je mó ìgbésí ayé èyà kan láti ìran dé ìran. Òwe máa n se àfihàn ìhà tí àwon ènìyàn àwùjo kan ko sí ìhùwàsí àti ìsesí èdá tí won faramó àti èyí tí won lòdí sí.

Àwon àgbà ní í sábà máa n fi òye àti ìrírí ayé won kó irú òrò tí a pè ní òwe wònyí jo láti máa fi se èkó fún àwon tí kò ní ìrírí ayé tó tiwon. Bí ìrírí ayé ènìyàn bá ti pò tó ni yóò se ní ogbón àti ìmò ìjìnlè láti fi òye fa òwe yo nínú ìrírí rè. Àwon àgbàlagbà ní í sábàá pa òwe. Ìdí ni pé bí a bá pé láyé, mérìíyìírí nnkan ni à á rí, bí a bá pé ní àkìtàn, a máa n rí abuké esinsin. Nípa pípé láyé ni àgbà fí i ní ìrírí ayé ju omodé lo. Yorùbá sì ní bí omodé bá ní aso bíi àgbà, kò lè ní àkísà bíi àgbà. Ìrírí ayé ní í jé àkísà àgbà.

Yorùbá bò wón ní bí òwe bí òwe ni a máa n lu ìlù ògìdìgbó, ológbón níí jó o, òmòràn ní í mò ón, ewé kókò ni awo rè, ganmugánmú ni a fi í lù ú, kò gbodò má dùn-ún, béè ni kò gbodò fàya. Ológbón ènìyàn ni Yorùbá ka eni tó bá mo òwe àti ìlò rè sí. Òpè èdá ni Yorùbá ka eni tí kò mo òwe sí. Èwè, àwon àgbà mìíràn wà tí won kì í fi iyè sí nnkan, won kò ní èbun bí a se lè to nnkan pò nínú ìrírí àwùjo won. Won kò lè fi làákàyè ya nnkan sí òtò láti sèdá òwe tó ní láárí. Ibè ni a sì ti rí omodé mìíràn tó máa n hùwà bíi àgbà. Wón fi ara balè, wón sì sún mó àgba, nípa báyìí, wòn máa n se ìse àgbà. Ìgbà tí a bá fi òye se èdá gbólóhùn tó fa ogbón yo nínú ìrírí àti ìsèlè tó n selè ní àyíká wa ní ònà tí òtító inú rè kò lè yípadà bí ó ti wù ká yè é wò tó ló di òwe.

Page 12: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

NNKAN TÓ MÚ ÒWE SE PÀTÀKÌ

Òtító àti ìjìnlè ogbón ni òwe máa n fi í hàn nígbà gbogbo. Àwon tí a bá fi òwe so òrò fún kò lè bá iró níbè bí ó ti wù kí won yè é wò tó. Àmó ìmò mò-ón-ko-mò-ón-kà àti òlàjú òde òní ti mú kí ìgbà lu àwon òwe kan ní àwùjo Yorùbá. Bí àpeere, “Ìkòríta méta tí í dààmú àlejò”. Pátákó ajúwe nnkan tàbí ajúwe ònà (sign board) ti mú kí òwe yìí so ewà àti ìtumò rè nù nítorí pé a ò dààmú bíi ti àtijó mó kí a tó mo ònà tàbí ibi tó ye ká yà sí nígbà tí ìrúnilójú bá selè lóde òní. Àpeere mìíràn ni: “Ó kojá onírú oko kó tó sé pón-ùn kan sí owó eyo”; “enu ko ìròyìn, ibi tí àkàrà pón-ùn kan je èko dé”, “òrò pò nínú ìwé kóbò (ìwé Ìròyìn), a kà á, kà á, kò tán mó”, “má tùú u, má yè é wò, òpin àkàsù kò ju tóóró”, “oògùn àlè bíi pón-ùn kan kò sí, àsàpé (aséwó) tí yóò ra okò ayókélé, yóò so ìyámòpó di awo”, áwónlójà bíi èsun isu”, àti béè béè lo (a.b.b.l).

Nítorí pé òwe jé òtiító òrò ni àwon àgbàlagbà se máa n fi wón kó àwon ènìyàn, yálà omodé tàbí àgbà ní èkó láti fi ìdí òrò múlè. Àwon àgbà n lo òwe láti fi hàn pé òtító ìgbà ìwásè tí kò yè rí ni nnkan tí won bá fi so fún ènìyàn. Òwe tó bá bá òrò tí à n so mu máa n jé kí òrò náà ní iye lórí ní etí àwon tí ó n gbó o ju ìgbà tí ènìyàn bá n so òrò ní gberefun lásán lo. Yorùbá ní amòràn-mo-òwe níí làjà òràn. Òwe ni à á fi í mo Ológbon tí í di orí eja mú, òmòràn tí í mo oyún ìgbín nínú ìkarahun, àti ògúnná gbòngbò tí í dátó lénu ìgbín nínú èdè Yorùbá nígbà yówù tí a bá n yanjú òrò tó takókó ní àwùjo.

Bí òwe se le mú kí òrò ní iye lórí, béè ni ó tún máa n ya àwòrán òrò fún olùgbó ní ònà tí nnkan tí à n so yóò fi yé e dáradára. Ènìyàn tó bá mo òwe í pa, tí o mo ìlò rè, tí ó sì tún mò ón túmò ni a lè pè ní Asòròfakòmóòkun-òrò-yo tàbí Apabì-yo-àbìdun òrò. Irú ènìyàn béè ni a tún máa n so pé ó ní pàkúté (tàkúté) èdè Yorùbá ní enu. A kì í fé kí irú ènìyàn béè dáké mó bí ó bá n so òrò ní àwùjo.Òwe ni a fi í mo èdá tó gbófá èdè Yorùbá yanranyanran. Bí ènìyàn bá wà tó mo òwe é pa dáradára, àmì àgbà ni. Bí ènìyàn bá wà tó mo òwe, mo ìtàn, tó tún mo àsàyàn òrò Yorùbá pèlú rè, àpeere, pé ó ti bá àgbà rìn ó sì tún towóbo àwo kan náà bá àgbà jeun ni.

Yàtò sí èyí, ànfààní tó wà nínú kí itó òwe àti àsàyàn òrò Yorùbá dá lénu ènìyàn kò k’eré rárá. Òwe kì í jé kí á fi òrò sòfò, kì í jé kí ohun ti a bá n so dojúrú létí olùgbó, ó máa n fa kòmóòkun (ìtumò abénú tàbí ìjìnlè) òrò yo ni.

ÒNÀ TI ÀWON ÀGBÀ FI N KÓ ÒWE JO

Page 13: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

Òwe jé àlàyé òfin tí kì í yè nípa ìhùwàsí èdá, àti nípa bí nnkan ti n tè lé ara won gégé bí àkíyèsí ti àwon àgbà n se tàbí èyí tí won gbó ní enu àwon asíwájú.

Síwájú sí i, àwon àgbà tún máa n fa òwe yo láti inú Odù tàbí ese ifá, ofò tàbí ògèdè, àyajó àti àwon àkójopò àsàyàn òrò Yorùbá mìíràn. Òké àìmoye òrò ogbón ló wà nínú àwon nnkan tí a dárúko wònyí.

Eni tí kò mo òkankan nínú àwon nnkan tí a dárúko yìí náà lè sèdá òwe bí ó bá farabalè, tí ó sì fi ojú sílè, tí ó n se àkíyèsí orísìírísìí ìhùwàsí, ìsesí, àti ìsèlè àwùjo. Bí àpeere, ènìyan kan ni ó se àkiyèsí pé kò sí bí a ti lè ju òkúta sí òkè, kí ó má padà wá sí ilè. Bákan náà ni àkíyèsí fi hàn pé bí ewé bá já bó ní orí igi, tí atégùn sì gbé e lo sí ojú sánmò, kò sí bí aféfé ti le gbé e jìnnà tó, ònfà ilè máa fà á wá sí ilè. Ìdí nìyí tí a fi máa n so pé lááláá tó lo sí òkè, ilè ni ó n bò. Òwe mìíràn tó tún jo èyí ni bí okò lo sí òkun bí okò lo sí òsà, ó di dandan kó padà wá foríbalè fún elébùúté.

Òwe kò pin sí ibi kan rárá. Ìdí nìyí ti a fi máa n rí òpòlopò òwe tuntun mìíràn yàtò sí ògòòrò tó ti wà ní àwùjo. Àkíyèsí tí àwon ènìyàn se nípa èéfín ló fi hàn pé èéfín kò lè déédé máa rú láìsí iná. Òwe jé òkan pàtàkì nínú lítírésò alohùn Yorùbá.

BÍ ÈNÌYÀN SE LÈ NÍ ÌMÒ TÓ MÚNÁDÓKO NÍPA ÒWE YORÙBÁ

Orísìírísìí ìgbésè ni ènìyàn lè gbé láti ní ìmò tó yè kooro nípa òwe Yorùbá. Òkan nínú ìgbésè tí a lè gbé láti ní ìmò nípa òwe ni kí a máa fi ara mó àwon àgbà. Tí èniyàn bá n dúró ní ibi tí àwon àgbààgbà ti n so òrò tàbí parí ìjà láàrin ènìyàn méjì tàbí jù béè lo, orísìírísìí òwe ni wón máa n lò nínú orò tí won bá n so. Bí ènìyàn bá fí etí sílè dáadáa, èkó púpò ni a lè kó nínú bi àwon àgbà se n lo òwe nínú òrò won.

Nnkan mìíràn tó tún lè ran ènìyàn lówó láti ní ìmò tó kún nípa òwe Yorùbá ni kí a máa tétí sí àwon apohùn tàbí akéwì ìbílè tí won jé agbáterù àsà àti ìse Yorùbá. Kì í se èkó kékéré ni a lè kó nípa ògòòrò òwe àti àsàyàn òrò tó máa n je jade nínú orísìírísìí ewì tí won máa n ké.

Page 14: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

A tún lè ní ìmò púpò nípa òwe Yorùbá bí a bá n fetí sí orísìírísìí ètò Yorùbá tó máa n wáyé nílé isé asòròmágbèsì (rédíò) àti móhùnmáwòrán (telifísàn). Àpeere irú ètò béè ni “Èyí Àrà”, “òwe àti àsàyàn òrò” ní ilé isé rédíò ìpínlè Òyó. “Òrò kò ní ilé ní ilé isé rédíò ìjoba àpapò tó wà ní ìlú Ìbàdàn, “Èrò yà” àti “májìyàgbé”, ní ilé isé rédíò àti telifísàn ìpínlè Òsun.

Síwájú sí i, a lè ní ìmò kíkún nípa òwe Yorùbá bí a bá n ka ìwé lítírésò Yorùbá tó wà lórí àte. Àpeere irú ìwé lítírésò tó lè ran ni lówó láti ní ìmò nípa òwe Yorùbá ni: Efúnsetán Aníwúrà, Óle Kú, Kòseégbé, Abé Ààbò, Òlú Omo, Ayé ye Wón Tán láti owó Òjògbón Akínwùmi Ìsòlá; Réré Rún, Àjà Ló-lerù, Àgbàlagbà Akàn, Àtótó Arere láti owó Alàgbà Oládèjo Òkédìjí; Omo Olókùn Esin àti Basòrun Gáà láti owó Adébáyò Fálétí. Èyíkéyìí tó bá wà ní àrówótó wa nínú gbogbo ìwé lítírésò Yorùbá náà ló wúlò, kò sí èyí ti a lè kà nínú won, tí a kò ní í bá òwe Yorùbá pàdé nínú rè.

Olùkó èdè Yorùbá tó ní ìmò nípa òwe Yorùbá, tí ó sì n se àmúlò òpòlopò won nínú ìdánilékòó rè náà tún lè ran akékòó lówó láti ní ìmò nípa òwe àti àròfò enu Yorùbá mìíràn.

BÍ A SE MÁA N LO ÒWE

Tí àgbàlagbà bá fé so òrò ní ònà tí ó jé pé ìwonba ènìyàn tí ó ní ìrírí tàbí ìmò ni ó fé kí ó mò nípa rè, ó lè lo òwe láti so nnkan tó bá fé so. Àgbà ló ni òwe, omodé ló ni àló, àgbà ló ni ìtàn, omodé ló ni orin.

Kì í se pé omodé náà kò lè pa òwe, sùgbón ó gbódò júbà àwon àgbà nígbà yówù tó bá pa òwe, pàápàá jù lo níwájú àwon tó jù ú lo ní ojó orí àti ipò. Ìdí nìyí tí omodé fi máa n so ìpèdé bíi: Yorùbá bò wón ní – kí ó tó pa òwe níwájú àwon àgbà. Bákan náà ni omodé tún máa n so ìpèdè bíi: “Kí òwe náà jé ti èyin àgbà”, “tótó ó se bí òwe o”, nígbà tó bá pa òwe níwájú àwon àgbà. Àwon àgbà náà yóò sì wúre fún omodé náà pé yóò rí òwe mìíràn pa. Se a kì í ra owó fé èpà tán kí ó tún jó ni lówó. Yorùbá ni àdáse ní í hun omo, ìbà kì í hun omo èniyàn, bí ekòló bá juba ilè, ilè á lanu fún un, bí omodé bá juba àgbà, á dára fún un, kò sì ní í sìse.

Orísìí ònà ni a lè gbà lo òwe, sùgbón a gbódò lò ó ní ònà tí yóò fi bá nnkan tí à n so mu. Bí àpeere, tí ènìyàn bá n se ìgberaga, tí ó n se bíi eni pé òun gbón tán, òun mò tán àti pé òun níkan ni a dá ilé ayé fún, a lè so fún irú eni béè pé “ewé odán se jù béè lo, eran ewúré ló fi se oúnje je”. A tún lè so fún eni náà pé “lááláá tó lo sí òkè, ilè ní ó n bò”. Bí òdó kan bá n fi àgbàlagbà se èsín, tí ó n rí àwon asíwájú rè fín, tí kò sí gbórò sí won lénu, a lè pa òwe yìí fún un

Page 15: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

pé “arúgbó se òge rí, àkísà lo ìgbà rí, ìgbágó tí n fi àgbà òpe se èsín náà n padà bò wá di àgbélèhe. Òwe mìíràn tí a lè pa fún un ni “omodé tí o ra ajá, tí ó so orúko rè ní ti àgbà kò ní í se, orí àgbà kò ní í jé kí ajá náà yè”.

Òwe máa n rorùn láti fi se àlàyé òrò fún ènìyàn nítorí pé ó je òtító. Bí òrò bá ta kókó, òwe ni àwon àgbà fi í yanjú rè. Ìdí nìyí tí a fi máa n pa òwe pé “Òwe ni esin òrò, bí òrò bá sonù, òwe ni a fi í wá a”.

A lè lo òwe láti gba ènìyàn ní ìmòràn. Bí àpeere: Ìsé ni oògùn ìsé, ènìyàn tó jókòó de ìsé yóò mo bí jábálá ebi ti í já mó ènìyàn lára. Òmíràn ni: a kì í pe ènìyàn ní olè kí ó tún máa gbé omo eran seré.

Òwe tún wúlò fún ìsírí. Bí àpeere, “àmódún kò jìnnà, kí eni má hùú èbù isu sun je”. “Ajá tí o pa Ikún ní òní lè pa Òyà ní Òla, nítorí náà ki a má bínú pa ajá” àti “pípé ni yóò pé, akólòlò yóò pe baba” jé àpeere àwon òwe tó wà fún ìsírí.

Bákan náà ni a lè fi òwe se àlàyé òrò fún ènìyàn. Bí àpeere, “Òpò ènìyàn ní í jé jànmó-òn, eni kan kì í jé àwádé o”. Àpeere Òwe mìíran tí a tún lè lò láti se àlàyé òrò fún ènìyàn nìwònyí: a kì í ni eni ní ìdí osàn kí a mu kíkan, eni tó bá ní baba ní ìgbéjó kì í je èbi, à ní kí a wá èniyàn tó ní èyìn fi omobìnrin fún, abuké bó sóde, terù èyìn rè ni à n wí bí? Olá àbàtà ní í mú odò sàn olá baba ní í mú omo yan.

Síwájú sí i, a lè lo òwe fún ìbáwí àti Ìkìlo. Bí àpeere, “bí a kò bá te aso àgbà mólè, àgbà kì í bínu”, “à n gba òròmodìe lówó ikú, ó ní won kò jé kí òun lo sí àkìtàn lo jeun”, “omodé lówó lówó, ó ní òun dìgbò- lu-èsù, òun àti owó rè, èwo ló tó èsù ú mu èko?”.

Ó se é se kí á lo orísìírísìí òwe kan soso fún ìbáwí, Ìkìlò àti béè béè lo. Ohun tí ó se pàtàkì ni pé ìlò àti ìtumò òwe tí a bá pa gbódò bá ìsèlè tó selè tàbí òrò tí à n so mu, kí ó sì jé isé tí ó ye kí ó jé fún olùgbó tàbí àwon tí a fi òwe náà sòrò fún.

Page 16: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

DÍÈ NÍNÚ ÒWE YORÙBÁ

Kì í se ìlànà alífábéètì (abídí) Yorùbá ni ònkòwé tèlé láti ko òwe wònyí sílè. Bí Ó se gbó won àti bí won se n wá sí i lókàn ní ení tere, èjì tere ni Ó se ko wón sílè.

1. Àgàn tí n gbé omo orogún rè jó, ó ye kí a kí i kú ìrójú (Ojú ló n ró).

2. Obè tó ní epo lójú ní í mu ènìyàn pón èyìnkùlé owó lá.

3. Ènìyàn tí Gàmbàrí bá rí je lódò rè ní í pè ní Mègídá.

4. Olórun kì í se nnkn kó má fi àyé opé sílè, bí ó bá pá ènìyàn ni orí, a sì fi irungbòn rópò rè.

5. Kò sí eni tí Olórun kò se fún, àfi ènìyàn tó bá ní ti Òun kò tó, Ó se fún adéte ó pa èékánná rè mó, Ó se fún akúwárápá, Ó n subú lulè nígbà gbogbo.

6. Ènìyàn tí kò bá ju ewé èbà nù léyìnkùlé Adébísí, kò lè pè é ní Olówó Ìdí-ìkán.

7. Nnkan tí a bá je ni a má a su, òkéré je eyìn, ó su ihá.

8. Ògbègí se aremo fún àgàn, àgàn n yò, àgàn, gbàgbé pé eni tó se aremo fún ni lè pa ni lómo bí a bá di olómo.

9. Ekún àgbélésun kò dé ilé olókùú

10. E kí baba òkóbó pé ó kú ìfàtó se òfò, e kí ìyá rè pé ó kú àdánù omo.

Page 17: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

11. Adègère kò rí se ní òsà, àgùntan kò rí je nínú èèpo isu ìgángán, ewúré wo ilé àpón, ó ju ìrù féfé, kí ni omo ènìyàn rí je débi pé yóò sé kù fún omo eranko.

12. Omodé lówó lówó, ó ni òun dìgbò-lu- èsù, òun àti owó rè, èwo ni ó tó èsù mu èko?

13. Omo odó pa ni télè kí a tó wá so pé a so ondè mó on.

14. Àpárá abé òdèdè kò dè ààfin.

15. Ogún odún ni mo gbé ní Sakí, kò pé kí á mo oògùn.

16. Ara àyájù ehoro fi epòn lé orí okó.

17. Eni tó bí ni kò tó eni tó wo ni dàgbà, eni tó bá wo ni dàgbà ni à á fi ìwà jo.

18. Èyin owó ní í se òfófó obe tó bá ní epo lójú, irungbòn ni a fi í mo ewúré tó ní ìfé oko rè.

19. Ìyá ni wúrà baba ni díngí, ojó tí ìyá bá kú ni wúrà bà jé, ojó tí baba bá kú ni díngí omo wo omi.

20. A kì í ní iwájú kí a má nìí ìpàkó, ìpàkó ni ilé ìyá, iwájú ni ilé baba eni.

21. Àpón sàn ju òkóbó.

22. Òkánjúà onígbàgbó ní í jé Sàámú, nnkan tó bá kángun sódo eni ló ye ká nawó mú nínú àwo.

Page 18: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

23. À n gbàdúrà pé kí àgbààná má wo owó eni, Ológbòn sílè n se àmín, ìgbà wo ni àgbààná fi í wo tóró- kóbò?

24. Omodé lówó lówó, wón ní ó n se àfojúdi, sebí owó òhún náà ni àgbà kò ní tí ó fi di àgbà ìyá.

25. Òkóbó ròyìn òbò lódì, ó ní òun fi bò ó, òun yín in kùnín-ìn.

26. A tún lè so pé: òkóbó sòró méji, ó fi òkan pa iró, ó ní òun fi bò ó, òun yín in kùnín-ìn.

27. Ìwà ni ewà, kí a lówó lówó láiní ìwà kò pé.

28. E jé kí a fi epo okòó je àgá nítori pé bí a bá je àgá tán (láì fi epo je é) ipá epo okòó kì í ká a.

29. Ológbón ni yóò kíyèsí i, asiwèrè a ní kín ni ó selè?

30. Omo kékeré ní í sí ogun, àgbà ní í jà á.

31. Bí Omo ilé bá si òpe ko, baálé ilé ní í bèbè fún un.

32. Ohun tó bá so baále ilé di erú, e béèrè lówó ìyàwó rè.

33. Erin ibi kan, èlírí ni ni ibomíràn

34. Ikú ti i pa alángba kò ju orí èékánná.

Page 19: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

35. Olórun tó dá ajá tí n je egungun eran lóríko, òun náà ló dá èyi tí n wo jàkáàdí léyìn Ìgbétì.

36. Òkéré n sunkún àìrí aso wò bàbá rè àjao tí ó fi tirè dá agbádá, igi ló fi n gùn nínú igbó.

37. Bí Àkárìgbò bá mo bí orí abéré, olórí Ìjèbú Rémo ní í se.

38. Bí a bá so fún igún pé orí rè pá, tí a sì so fún àkàlàmàgbó pé ó yo gbègbè lórùn, kò ye kí a gbàgbé lati so fún ògòngò (baba eye) pé enu rè se gongo.

39. Igi tí òfàfà fi n táákà agbára nínú igbó kò tó ohun tí erin yóò fowó fà tu.

40. Olómole tó ní ijó parí, ara rè ló tàn, bí oníyàálú bá ní ijo tán ni àbùse bù se.

41. Òkéré tó so ìpá, dídùn inú ode ni.

42. Ìtàkùn tó ní òun yóò se bíi agbélèyaràrá, bó bá ta bíi rè kò lè dùn tó o.

43. Méjì ni ilé alángbá, bí kò bá gbé orí igi, a fi àlàpà se ibùgbé

44. Ìlèkè má jàá sí ilé, má jàá sí òde, ibi kan ni yóò sà já sí.

45. Kékeré ni a ti í mo omo tí yóò fi àgbò bo bàbà rè bí ó (baba rè) bá kú tán.

46. Bí a bá dòbálè fùn aràrá, kò ní kí a má ga bí a bá dìde.

47. Àwé ni olè, ará ibí ni erú, eni tí a fé mú sìn ní í jé ènìyàn wa.

Page 20: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

48. Ènìyàn tó gbé ajá tà tó fi owó rè ròbo, ó dájú pé ó ti rógun àbámò.

49. Ènìyàn tó gbé adìe tà tó fi owo re ra awó, ó ye kí a mò, pé olúwarè kò ní àròjinlè.

50. Eni tó kó ilé tó tún kan ààsè sì i, ti agbára kó, eni tó kó ilé koríko tí kò lè parí rè kì í se òle, Olódùmarè ní í fún ni ní oríyín níbi isé eni.

51. Òkè Ìrágbìjí má jèé kí n dáran akódà oba, ìwon ara eni ni à á mò.

52. Bí àdúrà bá mo bíi orí èékánná, ó yá ju èpé agbòn kan lo.

53. Kékeré èpè, kékeré ìre, ìre yá ju èpè lo.

54. Ogún ikún ogbòn àfè kò tó itan kan àgbonrin.

55. Ènìyàn tó bá je olú àràbà, tó tún je olú ògán, yóò mò pé olú orán kò lè ní adùn bèje.

56. Òrò tí a dì sínú ewé gbòdògì, bí ó bá dé inú ewé kókò yóò fà ya.

57. Ìbí tí inú n bí asé, inu kò gbodò bí ìkòkò béè.

58. Owó da aso iyì bo ara, àbùkù da aso èté bo ara, ènìyàn tó fé ní íyì kó tún lówó lówó, olúwarè yóò tepá mó isé.

59. Òrìsà tí yóò gbe ènìyàn kì í gba èmí eni.

60. Fúnrarè ni yóò fura, eni tí à n bá sòrò tí a kò bá sòrò mò, fúnrarè ni yóò fura.

Page 21: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

61. Obìnrin tí à n bá lòpò, tí ó n só, ó dájú pé nnkan tí yóò bí ni ó n bí yen.

62. Gbogbo omo oba kí í je oba.

63. Ènìyàn tó ní ile Ìdáná ni gbòngàn Màpó ní Ìbàdàn màa jé ní ègbé ilé òun, Olùwarè kò ní ilé í kó.

64. Obìnrin tí à n bá lò pò tì kò se àkeekè, ó fi pamó di ojo ìkúnlè rè ni.

65. Bí àmàlà bá le, à máa fi omi sí i, Ìgbà ló le kojá nnkan tí à á fi omi pò kó lè dè.

66. Ògá ni ìyá Múdà, ènìyàn ló bí tirè tí kò lè mú Òbe.

67. Ògá ni eni tí ó fi eku kó omo, ènìyàn kì í rí itan irú nínú obè.

68. Ògúngbè gbón omo rè náà gbón, Ògúngbè ní ó yo, omo rè ni òun kì í, Ògúngbè ní kí ni ó kì, omo rè ní kí ni ó yo.

69. Àsòròòyán-òrò ló pa baálè ahósusódó tí ó ní ibi tí òun bá ju isu í ni kí won fi odó gún (dípò kì ó so pé ibi tí òun bá ju isu sí nínú odó ni kí won fi odó gún), isu àkókó tó hó, ó só o sínú odó, èkejì ó so ó sí enu.

70. Ó dún wìn-ín kò dún wìn-ín, òròmodìe, kì í se egbé èfó yánrin nínú obé.

71. Ó kéré kò jé kí n fún o ní í so ni di ahun, kò tóbi ni kò jé kí n gbà á ni àgbàlagbà òkánjúà.

72. Ènìyàn tan ara rè je bíi Olómo kan, wón ní omo rè n seré lójú òpópónà okò ilè, ó ní èwo ni nínú won?

Page 22: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

73. Ògá ni aáyán tó dá agbádá, alántakùn tó fi gbogbo ojó ayé ta òwú, aso kín ni ó fi dá?

74. Ikú omo ni ògèdè í gbá kú, òkan soso ni mo bí, Yorùbá ní òun ní í ká won ní eyín òkánkàn.

75. Ikú ogun ní í pa akíkanjú, ikú odò ní i pa òmùwè, ikú ewà ní í pa òkín, ikú ara íre ní í pa odíderé, gbàyèwò ní í ba ìbon òyìnbó jé, mo dára mo dára ní í so ìdí omidan di awo.

76. Odò gbé omo Àró, Ejemu (ojomu) n kó omo rè ní odò wíwè, ó ti gbàgbé pé ki í se ònà kan soso ni ikú í gbà pa ni.

77. Bí ekùn bá wo ìlú gbé omo adétè, omo aráyé a ní a dúpé, olóríburúkú kúrò láàárin wa, ojó tí ekùn bá gbé omo oba, gbogbo ológun àti àgbà ode ìlú ni à á ké sí.

78. Ènìyàn tó ní aso tí kò mò ón lò àti eni tí kò ní rárá, egbéra ni wón.

79. Àgbònrín tó so ìpá, ayò ode ni.

80. Ònà kì í jìn kí onínú má mo inú.

81. Màlúù tó bá ní iké leýìn, dídùn inú alápatà ni.

82. Eni tí ó kórìíra ìwòsí kó má rìn ní ipasè àrífín.

83. Àgbà tí kò ke ohùn fo èsì òrò níbi tó ti n su imí èrú, ó dájú pé yóò ke itan sáré.

84. Ìgbònsè kì í se ègún, sùgbón bí ó bá yí ni ní esè, à ó tiro rè.

Page 23: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

85. Omodé jogún òbò, ó n yò, àìmo ikú tó pa bàbá rè ni, bí bée kó, ìbá be òbò wò kó tó ti okó bò ó, kó lè rí ikú tó wà lóbò obìnrin tí í pa ni.

86. Àwòdì gbómo àgbébò ómúra ìjà, ìran baba adìe kan pa àsá rí?

87. Olówó tó fi esè ko tó ta ìka, sé ó fé pe Olórun oba léjó ni?

88. Omodé tó ra ajá, tó so orúko rè ní ti agbà-kò-ní-í-se, orí àgbà kì í jé kí ajá náà yè.

89. Afétenu-eni-í-gbó tí í fi orúko eni so ajá.

90. Bí a kò bá te aso àgbà mólè, àgbà kì í bínú.

91. Eni tó bá lè dá eran tóóró ra je, òrò rè kúrò ní fà á kí á jo já a.

92. Mo mò-ón rìn kan kò sí bíi kí a je kí olóúnje je oúnje rè.

93. Ènìyàn tó bá lè gún iyán san iyán, a kì í dá èrù òkèlè bà á.

94. Elégédé ni òrò náà, kì í se nnkan tí obìnrin kò lè mò.

95. À n sòrò elégédé, e nì kí a má jèé kí obìnrin gbó, ta ni ó máa so elégédé di obè?

96. Ká wo ni wo ni ká má tètè mójú kúrò ní í fa gbé ojú re kúrò, kín ni o n wò lára mi.

97. Ènìyàn tó ní òtùtú òwú kò tó erù, ìwonba tí yóò fi tan iná ló mú ni.

Page 24: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

98. Erù tí Gànbàrí yóò rù, ìpá ni yóò kókó tá a, a ni àbókí òkúta ni ìwo dì sí ibè ni àbí èkùró?

99. Ojú ni í rí ojú se àánú ní í mu aboyún gba òré fún àpón.

100. Kò jé kí n gbádùn ni obìnrin í gba òré fún, a ní àwomó re pò, o sáà fé mú ti ojú re kúrò.

101. Èmi ni mo lowó mi níí ba owó omodé jé.

102. Títa ríro ni à á ko ilà, bí ó bá jinná tán ní í di oge.

103. N kò je nínú isé owó re lòle fí í ségun alágbára.

104. Àìlówólówó alágbára kì í jé kí a mo òle bú, sùgbón bó pé bó yá ti aláájò yóò san.

105. Ogún agolo gamale ni mo fí, ogbòn agolo kòrì kòrì ni mo lò, bí ó bá se pé bí isé se tó ni èrè se í tó, ó dájú pé olómolanke ni ìbá kókó là, bí ó bá forí rù, a tún fi èyìn pòn, bí ó bá rìn díè, a ní “ésò beè, e bá mi gbé e”, sùgbón ìbùkún Olódùmarè ní í mú ni í là láì fi ti làá-làá se.

106. Ìtàkùn tó so igbá ló so agbè àti elégédé.

107. Eni tó ní ìyàwó méjì tàbí jù béè lo tó n rúbo kí òun má rógun ejó, ebo iró ni ó n rú.

108. Omode kó ilé, à ní ìyá rè ló ràn án lówó, se òun nìkan lo ní ìyá?

109. Bí eégbon bá dì mó epòn ekùn, kì í se ajá ni yóò já a.

Page 25: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

110. Ó se èyin ni ní í mú omo èkósé gba òré fún ògá rè.

111. Olókùnrùn dínwó kí n dín oògùn, bí owó bá ti mo ni oògùn yóò mo.

112. Kí omi tó di obè, ó kéré tán, ó níláti ní ilá méta.

113. ‘Èye ni oba í fi orí bíbé se ní ojo ojà, olójà kan kì í mu èjè ènìyàn.

114. Nnkan eni kì í di méjì kí a bínú, bí i ká fi omobìnrin sílé ìwé oníwèé méwàá kó gbé oyún wá sí ilé kó.

115. Eranko tó gbón bíi ajá kò sí ní ayé, èyí tó ya wèrè bí i esin kò pò, ajá mo omo tirè fún ni omú, ó sì mo ti òyà á kì mólè, esin fomo tirè sílè, ó n pon omo olómo kiiri.

116. Bí a kò bá fi oògùn dán omo ìyá eni wò, ará ìta kì í bèrù eni.

117. Bí oògùn kò bá sí, aró kò ní í re aso.

118. Àgbà gbàngbà kí à n wí, eni tí Olúwa bá se ní ògo, ògo ni.

119. Oko tí yóò se ànfààní kì í ju ogójì ebè.

120. Ènìyàn tó sún ikun sórí ó fi pamó ni, bí kò bá padà wa ní ikun, yóò padà wà ní kèlènbè.

121. Bi owó eni bá ti gba ìgbàkugbà, enu eni kì í lè so òtító mó.

Page 26: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

122. Kò sí nnkan ti àgbà kì í gbà lówó eni, bí ó bá gba okó lówó eni, enu ni à á kàn án sí.

123. Wá gba àkàrà wá gba dùndú lomodé fi í mo ojú eni.

124. Bí isó omodé kò bá rùn tó, ti ìyá rè a sì ràn án lówó.

125. Èkòòkan ni à á rí Òsùmàrè, ojó tí a bá rí i, ó ye kí á wò ó ní àwòfín.

126. Ìró ni à n gbó, a kò fojú kan olúkòso.

127. Eni gbogbo ló mo ekùn, sùgbón ènìyàn mélòó ni ekùn fé mò?

128. Kòlòkòlò tó pa àkùko adìe eni tí kò gbé e lo, bí ó ti n dun ni náà ló tún n dùn-ún mó ni, olúwarè a ní “èyin omo, è ó rí nnkan lo ata sí lálé”.

129. Eni tó bá na omo baálè, ó ti sá isu òrìsà lókó.

130. Bí ayé bá wà léyìn aáyán yóò pa adìe.

131. Ènìyàn méta n jeun, eni kínní ni e jé kí á rora se obè yìí kí ó lè tó waa jeun, eni kejì ni n kò mò pé ìwo náà rí i béè, tí kì í bá se eni keta ni wón n bá wí, a se pé àìtètèsòrò rè ni ó jé kí ó rí béè, ìjáfara ni ewu.

132. Olórun Oba tó se àféèrí fún aáyan, òun náà ló se àrìnnàkò fún adìe.

133. Nítorí ológbon ni à á fi í dá aso omo òdòó balè.

134. Omi ba imú esin jé, òpò òjò ba àkùrò jé, ajá òyìnbó dára, o kú àtise ode.

Page 27: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

135. Bí èèwò kò bá pa ni, a máa pón ni láso.

136. Àìgbón ní èwe ni àdàgbà se wèrè.

137. Kàkà kí kìnnìún se akápò ekùn, oníkálukú ni yóò dá ode rè se.

138. Àìyànré kì í wú ni lókè epòn, oúnje nìkan ni kò se é má je.

139. Ìpónjú omo ní í mú àgàn dá àbá àbíkú, a ní bí òun bí omo ní àárò tó sì kú ní alé ó yá ju àgàn lo.

140. Ènìyàn tí yóò so iró di òtító yóò jagun enu.

141. Àyà ni à á fi í yan òré, àgbè tí yóò kó haúsá, oko rè yòó di ìgbòrò.

142. Àìfárí kì í se òbo ní túúlu.

143. Má kòó ebo, má kòó ebo, òpin ebo kan kò kojá ikú, kobì-kòbì kan kò kojá kòbìtà-kobita, béè ni òjò kò lè rò rò kó ko já èyí tó rò tó wólé tó tún wú òkú òle.

144. Alágemo tó n se jéjé, ikú n pa á ká tó wí òpòló tó n fi ojoojúmó jan ara rè mólè kí olójó tó dé.

145. Àkùko tí kò bá ní í ko, kékeré ni àwòdì òkè tí í gbé e léyìn ìyá rè.

146. Má mu ohùn mi lo sí òrun tí í yan gúgúrú fún egúngún.

Page 28: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

147. Ewúré kú ó fi ìsé sílè fún awo, bó wu omo aráyé, won a fi kan ìlù, bó wù wón, on a sun ún je.

148. Bí babaláwo gbó ifá bí kò gbó ifá owó yòówù tí a bá fi dàniyàn níwájú Òrúnmìlà, ti babaláwo ni.

149. Ohun tí ajá rí tí ó fi n gbó, kò tó èyí tí àgùntàn fi n se ìran wò.

150. Nítorí kí isu ó ma kùú àkúrun ni àwon àgbè fí í se ara won ní èbù.

151. Ekùn dá mi mo dá ekùn, a kò lè fi wé eni tí ológìnní kò ko lù rárá.

152. Ènìyan tí sànpònná bá pa ni àpatì, tojú timú rè ni yóò fín bàtá-bàtá.

153. N kò lè nìkan sùn, bí i ti oorun inú sàréè kó.

154. Oògùn àlè bíi ayókélé kan kò sí bí a bá ti ní òkan rè kí igba olómoge máa jé ni ni.

155. Ènìyan tó gba obìnrin òde kò jìnnà sí ikú, béè ni ikú kò jìnnà sí eni tí ode gbà lóbìnrin.

156. Onígbèsè tí kò bá gba èèmí-ìn, àdúrà kó má gba èmí eni ni à á se.

157. Ènìyàn ìbá mo ojó àsedànù ìbá máa fi gbogbo ojó náà sùn àsùnnara.

158. Kékeré ni wón pe kókó ìgbònwó, ó dàgbà tán ipá òrí kò ká a.

Page 29: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

159. Ogbón tí ológbò fi n se ode dára ju ti ajá lo, sùgbón ajá ní í mu eran wálé jù, gbogbo nnkan ló ni mímò-ón-se.

160. Níjó ogún pípín ni à á ja ogun, níjó ogun ni à á ja oògùn, ogún ati oògùn, kò sí èyí tí kò tó ó dá ogun silè nínú won.

161. Ìse rè ni, ìse rè ni tí odò fi máa gbé eni tí eyín rè ta jáde lo, èrín lomo aráyé yóò se bí ó n rín.

162. Ibi tí olómo bá ti n bá omo rè wí ni eni tí kò ní òbí ti máa n kó ogbón.

163. Bí a bá ní eranko tó ní ìwo lórí ni yóò pa ènìyàn kì í se bí i ti ìgbín.

164. O gbó èdè, o kò gbo èyò, o ní o kò gbó ohun tí aráyé n wí, èyò baba èdè.

165. Bí ebi bá n pa ni, inú a máa bí ni, bí ebi bá n pa ìyàwó eni, ojú a máa ti i, bí ebi bá n pa omo eni inú eni a bà jé.

166. Ènìyàn tí yóò fowórorí kú kìí se eré lo sí ibi tí òkéré tí n sè, nítorí pé bí kò bá se sèbé, a se oká tàbí paramólè.

167. Ènìyàn tó torí wúrà te òpá òtè wo ìlú bí ogun bá pa ni tán, a tún máa pa nnkan mìíràn mó on.

168. Ilè tí kò gba obì tí kò gba kòkó, ó di dandan kó gba èmi ni mo sá ni nnkan mi.

169. Obìnrin tí a bá féràn kì í ní àléébù.

170. Ìyàwó tí a bá féràn ni omo rè í wu ni.

Page 30: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

171. Esin tó ta bàbá náà ló fi ìrù lu omo.

172. Ayé tí esin kò rí jé, ìrùkèrè ìdí rè ní í je é.

173. Ilé tí Obìnrin bá ti n ké atótó aréére, igi arère ní í hù kányìn níbè

174. Obìnrin tó bá n gbó baálé ilé lénu, kì í se òré àwon tó n gbórò sí baálé lénu (kì í gbé inú ilé òhún dalé).

175. Àìlówólówó ní í mu baálé-balónà so pé e lò ó ro èfó ká fi jeun, kò sí eni tí kò mò pé námò ní í se omi tooro sí ni lénu.

176. Bí iná bá n jó, ilé òsanyìn ni à á sá sí, sùgbón nígbà tí iná wá sé nílé òsanyìn yìí n kó?

177. Àìsí owó ni kì í jé kí a je móínmóín yó, ta ni kò mò pé móínmóín dùn- ún je ju èko lo?

178. Bí owó bá fé run, se ni àá ràn án lówó, bí ìyàwó àfésónà bá ko ni, à sì lé ti inú ilé lo.

179. Ìsokùn baba oba, ìsokùn baba oba, oba n dé adé, ìsokùn n dé àketè.

180. Bí a bá ní ìwákúùwá ni à á wá nnkan tó sonù, sé bíi kí a máa wá odidi màlúù nínú pánsá ni?

181. Owó àpà ní í lékè erù, ológbón a fi tirè, sí ìtélè koto.

182. Oníjìbitì tó lo sí ilé oníwàyó, òmì ni won yóò jo ta.

Page 31: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

183. Nnkan tó se eni tó jí èbù tà náà ló se eni tó rà á tí kò san owó.

184. Oníjìbìtì kan kì í ná ojà.

185. Èégun òkèèrè, ó ti ní iyì tó òyìnbó, a dé abé rè tán, ó sú ni í je.

186. Bí a bá dífá afúye gege fún aáyan, tí a sì se ònà-ò-gbà fún adìe, ó dájú pé eni kan ni oògùn yóò jé fún.

187. Bí a bá n pilè olà, èrín ni omo aráyé í fi ni í rín.

188. Òkéré jo ikún, òyùnkùn sì jo ase, àdán kò yàtò sí òòbè ní ààjìn, tojú- timú ni a fi í jo eni tó bí ni.

189. Ènìyàn tí kò je àté rí kò lè mo iyì iyò, eni tí kò je àsán rí kò lè mo iyì eran, ènìyàn tó bá je ilá ní funfun ní í mo iyì epo pupa.

190. Àfilò ni oorun inú okò.

191. Obìnrinkóbìnrin kì í jé kí omo eni ó jo ni.

192. Bí a bá ní kí a má rìí èjé kí a má rìí èjé, kì í se bíi kí àgbònrìn máa sun nínú abà ode.

193. Bí omo kò bá jo sòkòtò, yóò jo kíjìpá, èyí tí kò bá jo ÒKAN nínú on, dájàsílè omo ni.

194. Àkóbì ìyàwó ìwòyí, Olórun oba níkan ló lè so baba nínú baba.

Page 32: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

195. Bí a bá ní ká se òfin omo àlè, ó dájú pé kì í se gbogbo obìnrin ló lè fi ògún rè gbárí.

196. Obìnrin tó bá fi Ìdòwú se àkóbí nílé oko, ó di dandan kó sàlàyé ibi tó bí ìbejì rè sí.

197. Ègbadìí kò pé kí awo má kùú, èye awo ni.

198. Àlùfáà tó gbàdúrà tán tó tún gun orí ga ìwàásù, isé owó osù rè ni ó n se.

199. Abéré tó nínú ogún ológún.

200. Eku asín ko ìwòsi lo fi se enu rè ní kàfó.

201. Kànnìké tìtorí oókan kun ìgbé (so iná sí ígbó), ó ní nitorí owó kó, ibi tí ó bó sí ni kò té òun lórùn.

202. Kò sí ibi tí kí í dùn lára eran, se ni à á ójú kúrò.

203. Bí a bá fi tòlótòló se oògun àté, irú eye kín ni ó fé pa?

204. Ènìyàn tó je panla tí kò ta eyín, bí irú eni bèé bá je gbèsè, boóyá ni yóò san án.

205. Omo tí ò bá mo ilé ìyá rè afi-ibi-sú- olóore Omo ni, èyi tí kò bá mo ilé bàbá rè, omo olómo ni.

206. Ìyà ònà méjì kì í je òkóbó, bí kò bá ní okó, yóò ní ònà oko.

207. Àbíku gún omú, ìyá rè n yò, sé ó ti rí omo tí yóò mú omú òhún ni?

Page 33: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

208. Ìyá tó bí òlé kò rómo bí, ènìyàn tó bí gbajúmò ló bímo.

209. Aàyè ni a á je Ogún ore, bi a bá kú omo eni ní í jogún eni.

210. Ète ni àkókó èrò ni èkejì, ohun tí a ó se ni èkéta.

211. Kókò ta, Kókò kò ta, aláyùn yóò yè é nídìí wò.

212. Ìwe àwèpò ní í mú omodé rí ìhòòhò àgbàlagbà.

213. Jádìí síhìn-ín jàdìí sóhùn-ún, bí a bá dé ojúde ilé baba eni, à á dúró ni.

214. Oyé ni yóò kìlò fún eni tó sán tòbí, ebi ní yóò se orò fún òle.

215. Óúnje kì í pé yán olóúnjé lójú ni òbo fí í fi oúnjè tí a bá fún un gbolè, a ní kinní burúkú yìí tún lè fé é gbà á padà.

216. Onísu n je isu, à ní ó Se enu yán- an án-an, àtisu àtenu, ta ni ó ni wón?

217. Fòfòrofoforo imú ìyàwó yá ju yàrá fìfo lo.

218. Adásínilórùn obìnrin òdògo, aládìe n wá adìe, Ó ní kí won jé kí Oko òun dé.

219. Ojú burúkú lonílé òtún fi í wo ni, ìmòràn ìkà ni tí òsì n gbà, ebo, kí a jáde nílé loníle òkánkán n rú, èyìnkùlé ní òtá wà inú ilé ni aseni í gbé, bí ikú ilé kò bá pa ni tòde kò lè tètè pa ni.

220. Bí okó eni bá se mo náà ni à á se é fi í se oko ìyàwó eni

Page 34: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

221. Okùnrin bi enu rírí bíi igbá ewe yíì ni wón su obìnrin yìí lópó fún, òun ni ó tó sí ni o.

222. Ayé kò ní owó, béè ni ayé kò ní esè sùgbón bí ó bá yí ni sí poro, a sì tún yí ni sí ebè.

223. Má sù-ún mó mi, má sùn-ún mó ìyáálé mi, ojú ara eni nìkan ni à á pààlè lé o.

224. Omodé kò mo iyì ìyámòpó, ó fi ojú rè bo eruku.

225. Ibi ti àgbàlagbà ti n sunkún àìróbòdó, omo kékeré n fi tirè gbón eruku.

226. Bí oko àti ìyàwó bá jà tí alàgàta bá parí rè fún won láìparí rè láàárín ara won, ó dájú pé won yóò tún ìjà náà jà.

227. Àbúrò re ra okò ayókélé, o ní ìwo kò ní í jé kó fi gbé o bí ó bá ya wèrè, ta ni yóò máa se “e dákun e bá mi mu un, è bá mi mú un àbúrò mi ni?

228. Bí àgbè ti wù kó tètè jí tó, oko ni yóò bá kùkùté.

229. Ogún Odún tí okó ojú irin ti n to ilè e kú iwájú ni yóò máa kí ilè.

230. Àìmo èyí tó kàn ní í mú ni fa iná mònàmóná sí inú ilé koríko.

231. Omo àlè ènìyàn ní íi rán alàgàta sí bàbá rè kó tó rí ojú rere bàbá rè.

232. Òré méjì, wón n tan ara won, aká (adétè) tó ní òun lè hun aso àti afójú tó ní òun lè gun kèké.

233. Àìsanra tó ajá ológìnní kì í se ti àìjeun ká inú, bí ìran rè se é mo ni.

Page 35: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

234. Ìbí ti inú n bí asé inú kò gbodo bí ìkòkò béè.

235. Kó wá kó lo ni iyì òsùpá, bí òsùpá bá ti di àrànmóju, kò ni iyì mó.

236. Eni tó sòkò lu àgbònrín se aájò obè.

237. Ìrírí ni baba ogbón àròjinlè ni baba ìmò, ká sòrò ká yo kòmóòkun rè ni í mú ni pegedé láwùjo àwon amò-ón- ún-mò-ón tè ti í ko omo ní igbá di ogóje ati èrò kò wá oja.

238. Ayé bà jé, olorì n naja oko.

239. Oníwárápá tó ní kò lè pa oun, iró ló pa; nnkan tó bá gbé ni sánlè láàárín ojà lè pa ni.

240. Asòpá tó ní ipá kò lè pa oun, iró ló pa, nnkan tó há ni ní itan meji lè pa ni.

241. Eni bá kiiri níí rógbón èrò tó bá rìn jìnnà ní í gbórò; alárìnká tí kò bá tètè síwó ni ojú re máa n rí mobo.

242. Eni tí kò bá ìsín sawo, tí kò bá ìkòrò sorò, bí abéré rè bá bó sókun, kò gbodò dá ìmòràn pé òun ó mú un.

243. Ó sú mi ó rè mí kì í se ode erin.

244. A kìì kí erú baba eni kí á nà tán, bí a bá na ese kan, à á ká òkan rò ni.

245. Ènìyàn tó bá ta àgbàdo ní àtàrérìn- ín, o di dandan kó dá èko àdásunkún.

Page 36: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

246. Èlírí kìí se omo eku, bí iran rè tí i mo nìyen.

247. Ìgbé kín-nkín léti àwo gbègiri, bójú bá kúrò níbè, okàn kò ní í kúrò níbè.

248. Ara ò ro ìgbín, eni tó hègbín ní tòun di èrò pèsè.

249. Ìyàwó kò tíì kú, ò n sírò owo obè.

250. Ènìyàn tó ju òkò lu àgbònrín, aájò obè ló se.

251. Ibi tí Olórun bá gbé gbègìrì sí là á kó eko lo.

ÌWÉ KÍKÀ FÚN ÀNIKÚN ÌMÒ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

Adéoyè, C.L. (1979) Àsà àti Ìse Yorùbá Ìbàdàn, Oxford University Press.

Ajíbólá, J.O. (1947) Òwe Yorùbá, Ìbàdàn Oxford University Press.

Délànò, I.O. (1966) Òwe L’esin Òrò, Oxford University Press.

Fádípè, N.A. (1991) The Sociology of the Yorùbá, Ìbàdàn, University Press.

Fálétí, A. (1972) Basòrun Gáà, Ìbàdàn, Onibon òjé Press & Book Industries (Nig.) Ltd.

Page 37: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

Fàléti, A. (1969) Omo Olókun Esin, Ìbàdàn Heinemann Educational Books (Nig.) Ltd.

Ìsòlà, A. (1970) Efúnsetán Aníwúrá, Ìbàdàn, University Press.

Ìsòlà, A. (1981) Kòseégbé, Ìbàdàn University Press.

Ìsòlà, A. (1983) Olú Omo Ìbàdàn, Onibon òjé Press & Book Industries (Nig). Ltd.

Ìsòlà, A. (1983) Abé Ààbò, Ìbàdàn, Oníbon òjé Press & Book Industries (Nig.) Ltd.

Ìsòlà, A. (1988) The Modern Yorùbá Novel: An Analysis of the Writer Art, Ìbàdàn, Heinemann Educational Books (Nig.) Ltd.

Ògúnsínà, B. (1992) The Development the Yorùbá Novel 1930-1975, Òjóò, Ìbàdàn, Gospel Faith Mission.

Okédìjí, O. (1969) Àjà Ló Lerù, Ìbàdàn, Longmans.

Òkédìjí, O. (1971) Àgbàlagbà Akàn, Ìkejà, Longmans.

Òkédìjí, O. (1973) Réré Rún, Ìbàdàn, Oníbon ojé Press & Book Industries (Nig). Ltd.

Olatunji, O.O. (1984) Features of Yorùbá Oral Poetry, Ìbàdàn, University Press.

Sóbándé, A. (1967) Ìwé Àtigbàdègbà Ni Àtàtà Yorùbá, Ìbàdàn, General Publication Section, Ministry of Education.

Page 38: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

ÒRÒ ÀWON ARÁ ÌLÚ NÍPA ÒNKÒWÉ

(1) Adébáre omo kékeré abìse àgbà níkùn, ìwo kò lè mo péráyé máa n badùn Yorùba re”.

- Àyìndé Olátúnjí (26/12/92).

(2) Adébáre bàbá olówe, yóò tún fi òwe dá wa lárayá lónìí.

- Arabinrin A. Odéwolé (Òsogbo 21-08-93).

(3) Inú mi máa n dún láti wá ni ibi tí Uncle B (Báre) bá ti n sòrò. Bí ó ba so gbólóhùn kan, yóò pa òwe méta ó kéré tàn. Yóò wá dá bí ìgbà tí kí í se Yorùbá kan náà ni a jo se ní Yunifásíti.

– E.S.B. Awoyemi

Olùkó èdè Yorùbá: Alvan Ikoku

College of Education, Owerri (1993)

Page 39: ÀLÀYÉ LÓRÍ ÒWE YORÙBÁ

(4) Ti Bùródá keji tó se M.C. àti ìdùpé ni reception lónìí yìí ga o. Nígbà tí ó n sòrò, ó wá dà bi eni pé èmi náà ki í se Omo Yorúbá mó kò jo òwe ko jòkan ni ó fi n so gbogbo òro re. Se ló dà bìí pé kó má dáké mó.

Atóléokoólomálo to se Olúyoko Ìgbéyàwó Arabinrin Bùnmi aya Adéníyì ni Òsogbo:

(21-08-1993).